Ìfihàn 1 nínú 4 Àjọ Ẹ̀kọ́ àti Àṣà (AFECO)

Ẹ Káàbọ̀ sí Ìkànnì Adéàbẹ̀kẹ́ Fábọ́lá Educultural Organization

Lára abala àfojúsùn wa ni mímú àwọn ọ̀dọ́ dàgbà nípa ṣíṣe, àwárí ẹ̀bùn wọn, àtì ìrónilágbára fún àwọn ènìyàn.

Ìfihàn 2 nínú 4 Àjọ Ẹ̀kọ́ àti Àṣà (AFECO)

À ń Ran àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ láti Ṣàmúlò Ẹ̀bùn wọn,

nípa Lílo Ọgbọ́n Àṣà àti Ẹ̀kọ́lóríṣìíríṣìí Ọ̀nà tó mú Ìdàgbàsókè Bá Àyíká Wọn. Àjọ yìí ń ró ọ̀dọ́ àti àgbà lágbára láti ṣàmúlò, ẹ̀bùn àbímọ tábí èyí tí wọ́n ní nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ wọn.

Ìfihàn 3 nínú 4 Àjọ Ẹ̀kọ́ àti Àṣà (AFECO)

À ń fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Wa ní Ìmọ̀ tó Kún Lórí Àṣà Ìmọ̀ Àyíká

À ń fún Akẹ́kọ̀ọ́ ní àǹfààní láti kọ́ láti kà, àti láti mọ tìfuntẹ̀dọ̀ àṣà to jẹmọ̀ àyíká èyí tí yóò jásí àṣeyọrí fún ọjọ́ ọ̀la wọn.

Ìfihàn 4 nínú 4 Àjọ Ẹ̀kọ́ àti Àṣà (AFECO)

Àfojúsùn Wa ni láti Ṣe Àkójọpọ̀ èdè Abínibí

Ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mú Èdè abínibí ẹni lò. Ìlèpa wa ni láti ṣe àkójọpọ̀ ẹ̀ka-èdè tàbí èdè abínibí, bẹ̀rẹ̀ láti ilé-ìwé alákọ̀bẹ́rẹ̀ àti ilé-ìwé gíga, ìmọ̀ nípa ewé àti egbò náà kò ní gbẹ́yìn. Èyí yóò máa wáyé nípa kíkọ sílẹ̀

Ta Ni Wa?

Ẹ káàbọ̀

A Kú ojúmọ́ ire Ire owó, ire ajé, ire ìfọ̀kànbẹlẹ̀ àti ire àìkú bọ̀rọ̀ bọ̀rọ̀ kó jẹ́ tèmi tẹ̀yin.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwárí ìmọ̀ ọ̀tun, láìdẹ́yẹ sí ẹ̀bùn-àbímọ́ ẹni, a máa gbéni dépò àṣeyọrí bí? Jọ̀wọ́ ṣe àwárí ẹ̀bùn-àbímọ́ rẹ lónìí!

Ohun Tí ń Mú Wa Kíró

Iṣẹ́ Wa Nínú Ọ̀rọ̀ Mẹ́ta: Èdè · Àṣà · Ìmọ̀

Èdè Náà

Létà, ìwọn ohùn, òwe àti ìṣesí ọ̀rọ̀ — ẹ̀wà àti ọgbọ́n tí ó wà nínú èdè Yorùbá.

Àṣà & Ìtàn

Ayẹyẹ, ìkíni, oúnjẹ, aṣọ àti orin — a ń kọ wọ́n silẹ̀, kọ́ni wọ́n, a sì ń ṣe ayẹyẹ wọn pẹ̀lú àwùjọ tí ó ń tọ́jú wọn.

Ẹ̀kọ́ & Ìwádìí

Kilasi fún ẹni kọ̀ọ̀kan, ìwé fún ìpele kọ̀ọ̀kan, àti ìwádìí tí ń so ìtàn àtijọ́ pọ̀ mọ́ ọjọ́ òní.

Láti Ilé Ìwé Wa

Àwọn Ìwé Tuntun Wa

Ì
Ìwé

Ìjìnlẹ̀ Èdè: Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìpìlẹ̀ Èdè Yorùbá

Wo Gbogbo Rẹ̀ →
K
Ìwé

Kíkọ Àti Kíka Èdè Yorùbá Fún Ìpele Àkọ́bẹ̀rẹ̀

Wo Gbogbo Rẹ̀ →
Tuntun Láti Ọ̀dọ̀ Wa

Àpilẹ̀kọ & Ìròyìn

Ẹ Darapọ̀ Mọ́ Wa

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí ń Bọ̀

Nínú Fótò Wa

Ìṣẹ̀jú & Ìrántí

Ẹ darapọ̀ mọ́ wa kí a le mú kí èdè Yorùbá máa wà

Bóyá ẹni jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́, olùwádìí tàbí enití ó fẹràn èdè náà — ayè wà fún yín ní ibí.

Kàn Sí Wá